Islam ni esin aanu, o si jina si gbogbo i fi'pa mu ni s'esin

L’ode oni o ti han wipe awon awujo nbe ti ko ni agboye to rin-le nipa awon eko Islam. Daju-daju awon agboye wonyi je yo lati ara alaye ti ko kun-na tabi iro ponbele nipa awon eko Islam. Awon ti won ni awon agboye (ti kon rin-le) wonyii ko ni ri awon ewa ti eko rere Islam mu wo awujo nitori pe agboye won ni pe “awujo ti o ba lo ofin esin yoo ma gbe igbe aye ifun pin-pin.”Amon o, lai fi ti awon ai-gboye wonyii se, awon eko to wa ninu awon ase Oluwa Algbara-Julo (ninu Al-Kurani) da lori ife, iteriba, aanu ati idajo ododo, o si jina si i fi’pa mu ni. Nitori eyi, itan Islam kun fun awon apeere iwa ifarada ti Ojise nla (SAAS) ati awon Oni mimo lateyin wa fi ba oniruru awon eniyan lo.

Awon eko inu Al- Kuran, eyi tii se ipinle Islam ati isiti pelu imona fun awon Musulumi, da lori akori ife, aanu, ike, ikora eni ni-janu, ifarajin ati alaafia.

Nitori naa Islam je idena fun gbogbo iwa ipa, ifun pin-pin ati rogbodiyan, o un nikan naa si ni ona abayo.

Sugbon nitori awon ero aito ti o je yo nitori aimo nipa awon eko Al-Kuran,  awon kan n polongo wipe awon eko Islam le ko ijamba ba awujo.

Sugbon o, ni awujo to n gbe pelu eko Islam:

• Ko ni si i fi ipa mu ni; alaafia, aanu ati ife pelu owo ni yoo j’oba.

• Awon oni suuru, alarojinle, onitiju, olododo, olufokantan ni yoo dide. Won yoo si maa je ki alaafia ati idunu gboro l’awujo.

•Awon eniyan elesin ati ero otooto yoo ma be ni irepo, ni’won igba ti won ko ba ko ipalara ba ijoba ati alaafia awujo. Awon eniyan yoo si maa jina si awon iwa ti o le mu ede-aiyede wa, eleyii ti se iwa aimokan

Bawo ni ipa eko Islam, tii se ona abayo fun ikorira, ede-aiyede ati ipinya, se wa ye?

Bawo ni awon anfani ipa eko Islam se je eko fun awon awujo isaaju?

Orisun Alaafia ati Abo: Awon Eko Islam

Al-Kuran je tira ti o so’kale lati se atona fun ona imona. nini tira yii, Allah pa ase iwa rere fun omo eda eniyan. Iwa rere yi da lori ife, ike ati aanu. Gbolohun “Islam” je yo lati ara “alaafia” ni ede larubawa. Islam  si je esin ti a muwa fun awon eda eniyan pelu erongba igbe aye alaafia lati je ki ike ati aanu Allah j’oba kari aye. Allah pe gbogbo eniyan si akiyesi eko Islam lati je ki ike, aanu ati alaafia kari aye. Ni Sura al-Bakara, ese 208, Allah pe awon onigbagbo ododo wipe:

Eyin Onigbagbo ododo o! Egba alaafia (Islam) ni agba-tan. E ma si se tele oripa Esu. Dajudaju ota to han ni o je si yin. (Sura al-Bakara, 208).

Ninu Al-Kuran, Olohun fi ye wa wipe “abo” awon eniyan ati “alaafia” laarin won le se fi lo le lati ara i maa gbe pelu awon eko Al-Kuran. Musulumi tabi elesin miran, enikeni ti o ba n lo pelu eko Al-Kuran, yoo ni ojuse sise dede laarin awon eniyan, yoo ma dabo bo awon alaini ati alaise,  yoo si maa ta ko gbogbo iwa obileje ni orile aye. Iwa obileje ni gbogbo ona ti mu abo ati alaafia kuro ni orile aye. Ifi ipa mu awon eniyan, pelu ero ati igbagbo ti won, fun idi kan tabi omiran je nkan ti ko si ni ibamu pelu eko Islam o si ma n fa iwa obileje l’awujo. Nitori naa, ni itele ofin “Allah ko ni’fe iwa obileje” (Sura al-Bakara, 205), Musulumi gbodo jina si iwa aito bayii. Musulumi ni ojuse ati dena awon eniyan ati iwa ti yoo mu idiwo ba alaafia awujo, lati pepe si iwa rere ati lati ko aida, lati mu ibaje kuro ni orile ati lati mu alaafia j’oba fun gbogbo eniyan. O han gbagba pe, enikeni ti o ba ni iberu Allah ko ni ko’pa ninu ise ti yoo ko ipalara ba orilede abi awon eniyan, bee si ni ko ni daju won pelu.

Pipe Ododo ni Iro ati Iro ni Ododo je ete Dajjal

Ni opin aye, orisirisi ero ati ise ti n mu awon eniyan lo sibi aigbagbo, jina si eko rere esin, ti o si tun da ede-aiyede sile larin awujo, je apeere Dajjal. Hadisi si se apejuwe Dajjal gege bi eni ti yoo da rogbodiyan sile l’orile. Ikan ninu awon itumo Dajjal ni “eni ti yoo ma da ododo po mo iro, yoo si maa fi iro han gege bi ododo.” Lara awon Hadisi ti o se apejuwe Dajjal gege bi eni ti n pe ododo ni iro ati iro ni ododo ni won yii:

“Leyin naa, Dajjal yoo de pelu omi ati ina. Enikeni ti o ba ti o ba wo inu ina re yoo si ri esan gba, eru re yoo si di fifuye. Ama enikeni ti o ba wo inu omi re ki yoo ri esan gba be si ni eru re ki yoo di fifuye.” (Sunan Abu Dawud. p. 4232)

“Yoo (Dajjal) si wa pelu paradisi ati ina pelu re. Bi o ti le je pe paradisi re yoo da bi al-jannah, l’ododo ina ni yoo je. Be si ni ina re yoo da bi Jahanama, sugbon l’ododo paradisi ni.....” (Sahih Muslim)

Bi awon hadisi se juwe re, awon nkan ti Dajjal ba mu wa bi nkan daada yoo je ohun ti yoo ko ipalara ati iparun  ba omo eda eniyan. Ewe, ohun ti o ba mu wa gege bi nkan aburu, yoo se awon eniyan ni anfaani. Sugbon, ni to ri awon eniyan miran ko fi eko al-Kuran ati Sunna Ojise-nla (SAAS) se osunwon, won yoo ro pe dajjal n pe awon si ohun ti yoo se awon ni anfaani ni won yoo si tele. Be si ni won yoo se d’eyin ko awon ti o ye ki won maa tele. Won yoo pada ri asise won nigba ti won ba kiyesi inira ti yoo j’oba ni awon latari i ma tele dajjal. Nitori eyi, Ojise-nla (SAAS) kilo o si pe akiyesi wipe ohun ti Dajjal ba fi han gege bi inira, l’ododo ohun dara dara ni:

“Dajjal yoo wa pelu omi ati ina atipe ohun ti awon eniyan ri gege bi omi yoo si je ina tii jo ni. Be si ni ohun ti won ri gege bi ina yoo si je omi. Enikeni ninu yin ti o ba se alabapade eyi, ki o be si inu ina re tori pe omi ni yoo je.” (Sahih Muslim)

Dajudaju, okan ninu awon ona ti Dajjal yoo gba pelu ete re nipe, yoo ma fi awon eko esin han gege bi ohun ti o nira, yoo si ma fi awon ilana tire han gege bi ohun ti o rorun. Awon ti ko ba mo awon eko al-Kuran tabi ti won ko ma lo igbe aye ye won pelu awon eko yii le jin si ofin awon ete ti Dajjal fi n tako esin, be si ni won ti le fere maa ni igbagbo ti ko to nipa awon eko rere Islam.

Apeere kan ti yoo han gbangba nipa Dajjal nipe, nigba ti o ba n pete awon aburu won yii, yoo ma pa iro wipe nitori erohungba dada ni. Gege bi hadisi ti se so, bi o ti le je wipe o fe tan aburu s’orile ni, yoo ma pa iro wipe o fere fe dada fun awon eniyan ni. Lai si ani...ani iro ponbele ni eyi je. Idahun ti awon onigbagbo ododo yoo maa fun ipe aburu  Dajjal, si igbe aye ti o jina si esin, wa ninu al-Kurani wipe:

Say: “Are we to call on something besides Allah which can neither help nor harm us, and to turn on our heels after Allah has guided us, like someone the satans have lured away in the earth, leaving him confused and stupefied, despite the fact that he has companions calling him to guidance, saying, ‘Come with us!’?” Say: “Allah's guidance, that is true guidance. We are commanded to submit as Muslims to the Lord of all the worlds.”(Surat al-An’am, 71)

So wipe:-se awa o ma pe nkan miran yato si olohun Allah ti ko le se wa ni anfaani tabi ki o pa wa lara,tabi ki awa see igbori gbonri lehin ti ati fi ona mo wa;gege bi eniti esu ti tanje ti ko si oun tonse bi oti le je pe oni awon ti oun pee pe wa si itosona ti won nsope “wa pelu wa”so wipe Itosona ti Allah ni itosona tooto.A si pa wa lase lati gba bi Musulumi fun olohun oba aye ati orun.(Al An am,71)

Ifaye gba Esin je nkan Gboogi ninu Eko Islam

Fi f’ipa mu ni se esin tabi gba igbagbo kan je ohun ti Islam lodi si. Ninu Islam, igbagbo tooto ko le waye ayaafi laisi ifi ipa mu ni ati wipe o gbodo je ohun ti inu yoo si. Beeni, Musulumi le pe ipe si awon eko al-Kurani. Gbogbo onigbagbo ododo ni oni ojuse ati ma se alaaye awon eko al-Kuran fun awon eniyan ni ona ti o rewa. Won yoo ma se eyi ni i maa tele aaya to so pe, “Pe ipe si oju ona Oluwa re pelu ogbon ati isiti ti o rewa…” (Surat an-Nahl, 125), sugbon, won gbodo mo oro aaya miran ni okan won wipe, “Ire ko ni ikapa lori imona won, sugbon Allah ni o n fi ona mo eniti o ba fe.” (Surat al-Baqara, 272).  Won ki yoo mu enikeni pelu ipa, be si ni won ki yoo di enikeni ni iponpon. Won ko ni fi ohun adun aye pe ipe esin nitori ojuse gbigba igbagbo owo onikaluku ni owa, gege bi Allah se pa’se. Allah pa’se fun awon Onigbagbo ododo ninu al-Kuran wipe:

A mo amodaju ohun ti won so atipe Ire [Muhammad] ki se olukapa lori won. Se ikilo fun won pelu al-Kuran fun enikeni ti yoo beru ikilo mi (Allah). (Surah Qaf, 45)

Awujo yoo wu ti won ba ti n fi ipa mu ni se esin lodi si Islam. Igbagbo ati Ijosin ko le se anfaani ayaafi ni iwon igba ti o ba je fun Allah lai si i fi ipa mu ni nibe. Ti eto ijoba ba kan esin kan tabi igbagbo kan ni ipa lori awon eniyan, won yoo gba esin naa lati ara iberu fun eto ijoba naa. Iha ti esin ko si iru oro bayi ni wipe, eyi ti o se koko julo ni ki awon eniyan josin lati ri iyonu Allah lai si ikan-ni ni ipa nibe.

Ko si i fi ipa mu ni loro esin. Otito ti fi oju han  gbangba yato si isina.       (Surah Al-Bakara, 256)

Ko si i fi Ipa mu ni ninu Islam

Islam je esin to fi aaye gba irori, adi-okan ati igbe aye. O fi ofin lele lati de naa aigbora-eni-ye, ija, egan ati ero buburu larin awujo. bee naa lo si lodi si iwa idun-koko ati gbogbo iwa jagidijagan. Koda o ta’ko i fi ipa mu ni bo ti wu o kere ma:

Islam is a religion which provides and guarantees freedom of ideas, thought and life. It has issued commands to prevent and forbid tension, disputes, slander and even negative thinking among people. In the same way that it is determinedly opposed to terrorism and all acts of violence, it has also forbidden the application of even the slightest ideological pressure:

Ko si i fi ipa muni loro esin. Otito ti fi oju han  gbangba yato si isina.        (Surah Al-Bakara, 256)

Se isiti fun won! Olusiti lasan ni iwo se. Iwo ko ni ikapa lorin okan won. (Surat al-Ghashiyya, 21-22)

 

Awon Apeere Aanu lati igbe aye Ojise Muhammad (SAW)

Awon Musulumi mo pe awon le jo’gun ike Allah ni’pase sise aanu, igbe alaafia and sise dede. Ni ibi imaa polongo eko Islam, Ojise nla (SAW) ba onikaluku lo pelu aanu ati alaafia, laise se adayori larin ikan kan won.

Nigbati Ojise nla (SAW) gba iro ije ojise, ile larubawa, ati ilu Mekka ni pataki julo, n mi titi pelu opolopo rogbodiyan. Ni asiko to siwaju igba alaafia, eleyin ni “Igba aimokan”, orisirisi ede-aiyede lo n sele nitori iwa eleya-meya ati elesin-o-jesin. Ija laarin iran si iran, oro aje ti ko gun rege, ikorira laarin ijo esin kan-kan, ipinya laarin awon oloro ati alaini ati awon aise dede bayi lo n waye lati ipase awon iwa eleya-meya ati elesin-o-jesin won yii. Idajo ododo ko fii idi mu’le; awon to wa ni ipo si n fi iya je awon alaini nitori iran, esin ati ede won. Awon eniyan n se ise pelu inira ati ije gaba lori won. Ojise nla (SAW) wa lati wa jise ododo fun awon iran alaimokan won yii ati lati pe won si ise rere. Ipepe Ojise nla (SAW) ati iwa rere re jo awon iran larubawa l’oju ogoro awon eniyan si gba esin islam ni asiko re. Awon ofin deede ti Qurani royin, iwa rere, aanu ati alaafia, mu eto ati ifokanbale wa si awujo. Ikan ninu awon idi pataki fun alaafia yi ni idajo ododo ti Ojise nla (SAW) fi lele laarin awon eniyan laise adayanri won. Eleyi ni o je’yo lati inu aaya yii, “Allah pa o lase.....se dede ni bi idajo.” (Sura An-Nisa’, 58)

Lehin ijira Ojise nla (SAW) lati ilu Mekka lo si Medina, O se konge orisirisi awujo. Ni asiko yii, awon Yehudi, Nasara ati awon Keferi to wa ni ipo n gbe papo ni. L’atari eleyii, Ojise nla Muhammad (SAW) fi eto ibagbepo lele fun irepo ati alaafia pelu sise adehun – ni’pase ifi iwe ranse tabi sise ipade – pelu awon ijo ti o le ni ogorun. (Muhammad Hamidullah, Introduction to Islam, Publications of Centre Culture, Paris, 1957, p. 228). Ojogbon Thomas Arnold fi pataki ibagbepo alaafia ti Ojise nla (SAW) fi lele pelu awon oro won yii:

“Ile larubawa ti ko fii igbakan tele ofin alase kankan, lojiji wa bere si se afihan isokan ati itele ase olori kan soso. Larin awon oniruru iran (ti o le ni ogorun) ti ko fi igba kan re tele ri, oro Ojise nla (SAW) wa gbe orilede dide.” (Prof. Thomas Arnold, The Spread of Islam in the World, Goodword Books, 2001, pp. 32-33)

Awon apere iwa rere wonyi to je yo lati ara bi ojise nla (SAW) se n tele ofin Allah tun fi aanu ati alaafia ti awon ojise muwa si awujo han. Awujo ti o ba mu eko Qurani de ogongo, o fi oju han pe igbe aye omo-iya ati alaafia se fi lole nibe.

Owo fi fihan fun awon ero ati asa miran lasiko awon Kalifa Ottoman

Igbese ti ose pataki julo ninu fifi ibagbepo ifayabale ati irorun lele ni awujo ni lati fi owo fun olukuluku ati igbagbo re, lai kan nipa fun-un lati gba esin, asa tabi isesi miran. Awon ijoba Ottoman to fi ilana ibagbepo to yanju lele je apere to rewa ti a si ri ninu itan.

Asiko awon Kalifa Ottoman je asiko igbadun fun gbogbo eniyan oniruru igbagbo ati ero otooto. Won si n gbe papo labe ijoba yii. Fun o le ni egbe-ta odun, oniruru eniyan, pelu asa, igbagbo, esin ati iran orisirisi ni o n gbe ni alaafia labe ijoba yii. Lasiko yi, ko si iyanje fun enikeni l’atari esin tabi iran won nitori pe ijoba awon Ottoman ko pataki igbe irorun ati alaafia fun awon Musulumi ati omo ile tooki nikan, sugbon fun gbogbo iran ati esin to fi ile naa se ibugbe. Lori ipile eko Islam, awon olori ijoba Ottoman se iranwo fun enikeni to je alaini, lai fi t’esin tabi igbagbo se. Won se eleyii to ri ipile ojuse won si Allah ni. Lati saa Osman Ghazi, to je oludasile ijoba Ottoman, Sultan Mehmed – Jagunmolu, ati awon olori miran di arikose fun gbogbo eda eniyan. Eyi je be nitori iwa rere won ati idajo ododo. Labe ase won, oniruru eniyan lo gbe papo ni alaafia. Siwaju si, awon ileto miran gba Sultan Mehmed – Jagunmolu ni olori, lai si atako kankan lati odo awon ileto bee, lai si si ifi ipa mu ni. Eleyi tun fi idi oro naa rin le wipe awon eniyan gbadun ijoba won.

Olukotan Richard Peters se alaye bi awon Musulumi ile Tooki se fi idajo ododo lo le ni awon orile ede ti won jagun gba:

“Fun ogoro odun, ijoba ile Tooki pase lori opolopo orile ede sugbon won ko pa asa won re. Won fun won ni anfaani idande won si fi won sile lati maa se esin, asa ati ise won. .” (Richard Peters, Die Geschichte der Türken, W. Kohlhammer Verlag, Stuttgart, 1961, p. 8)

Awon apeere wonyi fi han gbangba pe lori ile ijoba Ottoman gan-gan, oniruru iran, esin ati asa gbe po ni alaafia, lai si ija abi keeta kankan. Ti awon olori ijoba Ottoman ko ba se dede pelu awon eniyan wonyi ni, won ko ba ti le fi idi ijoba won mule fun igba pipe rara. Sugbon a ri wipe awon eko to pe ye ti Islam fi ke awon Olusakoso wonyi fun won ni anfaani ati le fi asa ati idagba soke to gban-gban lole.

Ni Ipari: Eko Aanu ati irepo awon Musulumi n so Awujo papo

Awon apeere inu akori oro yi ti fi han wipe awon Musulumi se ojuse ati fi anu ati ike ba awon orisirisi esin ati asa ti won ba gbe lo po. Nitori eleyii, ni itako aimokan ti o ti gbile ni isaaju, Musulumi ti a ba fi eko rere ti Qurani mu wa to, yoo fi ife ba awon eniyan lo po gege bi Islam ti se atona. Musulumi naa yoo ni iwa iba lo po rere ati ise dede. Ni awujo ti iru awon o ni iwa rere ba yii ba wa, o ti daju wipe idagba soke awujo, iwa pele, idunu, alaafia, idajo ododo, ifaya bale ati opo ni yoo j’oba.

Koko oro bawonyi ti ko fi oju han si awon eniyan, l’atari awon iro t’ojina si ododo ti won n gbo, je ki won maa ni awon ero ti ko to nipa Islam. Sugbon ni igba ti won ba ri ari daju wipe Islam se okunfa iba repo, ifi owo fun ni, atipe ko ta ko olaju, ti ko si fi ipa mu ni lori esin ati ero, won yoo tun iwa won ati ero won pa nipa Islam. Ninu aaya Qurani kan, Olohun Oba Alagbara Oni’ke wipe:

 “Wipe: ‘Ododo ti de atipe iro si ti poora. Daju-daju iro yoo ma poora ni. (Surat al-Isra’, 81)

 

Se isiti fun won! Olusiti lasan ni iwo se. Iwo ko ni ikapa lorin okan won.

(Surat al-Ghashiyya, 21-22)


2011-02-21 11:12:33

About this site | Make your homepage | Add to favorites | RSS Feed
All materials can be copied, printed and distributed by referring to author “Mr. Adnan Oktar”.
(c) All publication rights of the personal photos of Mr. Adnan Oktar that are present in our website and in all other Harun Yahya works belong to Global Publication Ltd. Co. They cannot be used or published without prior consent even if used partially.
© 1994 Harun Yahya. www.harunyahya.com - info@harunyahya.com
page_top